wọ́n ní ilé làá wò ká tóo s’ọmọ lórúkọ—
inú ilé tí ati bí'mọ. àmó ilé tí n ò bá wò
ni ó kún fún egbìrìn ọ̀tẹ̀ yìí—
ilé olórogún—ilé ogun. èmi–jù–ó–
ìwọ–ò–jù–mí, ti sọ ilé ọlá di ahoro.
ilé tí ò bu àpónlé fún ni—ilé tí oriki rẹ̀ ò ṣé mú yangàn.
àwọn ará iwájú ò rò ẹ̀yìn ọ̀la, wọ́n yí orúkọ mọ̀lẹ́bí mẹ́ẹ̀rẹ̀—
imí létí ọpọ́n ifá - àbùkù rèé lára ohun àpónlé.
wọ́n gbàgbé wí pé orúkọ rere, ó dára ju wúrà òun fàdákà lọ.
oníyangí ará iwájú tapo sí ààlà
àwọn èrò tó n bọ léyìn. orúkọ àpọ́nlé
wá dà ohun a ń ṣáá fún bíi aṣọ ẹlẹ́gbin.
bí aṣọ ẹ̀sín. nítorípé okùn mọ̀lẹ́í ti já.
nítorípé ilé tí a bá fi itọ́ mọ
ìrì ni yóò wo. ilé olórogún, ilé ogun.
orogún ń loogun ogun, ọbàkan ń gbómi ìjà k’aná
ilé ṣe bẹ́ẹ̀ ó di ajere — janjaanjan bíi iná ọtíkà.
ẹ sọ fún mi—pẹ̀lú àwọn àkàwé yìí—orúkọ wo ni kín s'ọmọ?
orúkọ rere wo ni n ba s'ọmọ
nígbàtí orísun rẹ̀ bá kún fún kìkì ẹ̀jẹ̀?